Desktop versionMobile Version

Universal Declaration of Human Rights: English, French, Hausa, Igbo and Yoruba

Ikede Kariaye fun Eto Omoniyan

Volltext

Oro Akóso

1Bi ó ti jé pé sise àkiyèsi iyì tó jé àbimó fún èdá àti ìdógba ètó ti kò seé mú kúrò ti èdá kòòkan ni, ni òkúta ìpìlè. fún òmìnira, ìdájó òdodo àti àlààfià lágbàáyé,

2Bi ó ti jé pé àìka àwon ètó omonìyàn si àti ìkégàn àwon étó wónyi ti se okùnfà fún àwon ìwà búburú kan, tó mú èri-okàn èdà gbogbé, td sì jé pé ìbèrè ìgbé ayé titun, ninu èyi ti àwon ènìyàn yóò ti ni òmìnira òrò siso àti òmìnira láti gba ohun tó bà wù wón gbó, òmìnira lówó èrù àti òmìnira lówó àìni, ni a ti kà si àniyàn tó ga jù lo lókàn àwon omo-éniyàn,

3Bi ó ti jé pé ó se pàtàkì ki a dààbò bo àwon ètó omonìyàn lábé òfin, bi a kò bà fé ti àwon ènìyàn láti kojú ìjà si ìjoba ipà àti ti amúnisìn, nigbà ti kò bà si ònà àbàyo mìiràn fun won láti bèèrè ètó won,

4Bi ó ti jé pé ó se pàtàkì ki ìdàgbàsókè ìbàsepò ti Òré_si-òré wà lààrin àwon orilè-èdè,

5Bi ó ti jé pé gbogbo omo Ajo-ìsòkan orilè-èdè àgbàyé tún ti tenu mó ìpinnu ti wón ti se télè ninu ìwé àdéhùn won, pé àwon ni ìgbàgbó nimú ètó omoniyàn tó jé kò-seé-má-nìí, igbágbó nínú iyì àti èye èdá ènìyàn, àti ìgbàgbó ninu ìdógba ètó láàrin okùnrin àti obìnrin, tó sì jé pé wón tún ti pinnu láti se ìgbéláruge ìtèsiwáju àwùjo ninu èyi ti òmìnira ètò ìgbé-ayé rere èdá ti lè gbòòrò si i, Bi ó ti jé pé àwon omo egbé Ajo-ìsòkan orilè-èdè àgbáyé ti jéjèé láti fowósowó pò pèlú Ajo náà, ki won lè jo se àseyege nipa àmúse àwon ètó omonìyàn àti òmìnira èdá tó jé kò-seé-mánìi àti láti ri i pé à n bowo fún àwon ètó náà káriayé,

6Bí ó ti jé pé àfi ti àwon ètó àti òmìnira wònyi bá yé ènìyàn nìkan ni a fi lè ni àmúse èjé yìi ni kíkun,

Ni báyìi,

7Apapò ìgbìmo Ajo-ìsòkan orilè-èdè àgbáyé sé ìkéde kàriayé ti ètó omonìyàn, gégé bi ohun àfojúsùn ti gbogbo èdá àti orilè-èdè jo ri lépa lónà tó jé pé enì kòòkan àti èka kòòkan láwùjo yóò fi ìkéde yìi sokàn, ti won yóò sì ri i pé àwon lo ètò-ìkóni àti ètò-èkó láti se ìgbéláruge ìbòwò fún ètó àti òmìnira wonyi. Bákan náà, a gbodo ri àwon ìgbésè ti ó lè mú ilosiwájú bá orilè-èdè kan soso tàbi àwon orile-èdè si ara won, ki a sì ri i pé a fi Òwò tó joju wo àwon òfin wónyi, ki àmulò won sì jé kàriayé láàrin àwon ènìyàn orilè-èdè tó jé omo Ajo-ìsokan àgbáyé fúnra won àti láàrin awon ènìyàn orilè-èdè mìiràn tó wà lábé àse won.

Abala kìini.

8Gbogbo ènìyàn ni a bi ni òmìnira ; iyì àti ètó kòòkan sì dògba. Wcn ni èbùn ti làákàyè àti ti èri-okàn, ó sì ye ki won o máa hùwà si ara won gégé bi omo ìyà.

Abaia kejì.

9Eni kòòkan ló ni anfani si gbogbo ètó àti òmìnira ti a ti gbé kalè ninu ìkéde yìi láìfi ti orò ìyàto èyà kankan se ; ìyàtò bí i ti èyà ènìyàn, àwò, ako-ñ-bábo, èdè, èsìn, ètò ìsèlu tabi ìyàto nipa èro eni, orilè-èdè eni, orirun eni, ohun ini eni, ibi eni tabi ìyàto mìiràn yòówù kó jé. Siwájú si i, a kò gbodò ya enìkéni sótò nitori irú ìjoba orilè-èdè rè ni áwüjo àwon orilè-èdè tábi nitori ètò-ìsèlú tábi ètò-ìdájó orilè-èdè rè ; orilè-èdè náà ìbáà wà ni òmìnira tábi ki ó wà lábé ìsàkóso ilè mìiràn, won ìbáà má dàá ìjoba ara won se tàbi ki wón wà lábé ìkàni-làpà-kò yòówù ti ìbáà fé di òmìnira won lóWó gégé bi orilè-èdè.

Abala keta.

10Eni kòòkan ló ni ètó láti wà láàyè, ètó si òmìnira àti ètó si ààbò ara rè.

Abala kerin.

11A kò gbodò mu enikéni ni erú tábi ki a mú un sin ; erú nini àti òwò eru ni a obodò fi òfin dè ni gbogbo ònà.

Abala karùn-ún.

12A kò gbodò dá enìkèni lóró tábi ki a lò ó ni ìlò ìkà ti kò ye. omo ènìyàn tàbi ilò tó lè tàbùkù èdá ènìyàn.

Abala kefà.

13Eni kòòkan ló ni ètó pé ki a kà á sí gégé bi ènìyàn lábé òfin ni ibi gbogbo.

14Abala keje.

15Gbogbo ènìyàn ló dógba lábé òfin. Wón sì ni ètó si ààbò lábé òfin láìsi ìyàsòtò kankan. Gbogbo ènìyàn ló ni ètó si ààbò tó dógba kurò lówó ìyàsótò yòówù ti ìbáà lòdi si ìkéde yìi àti ètó kurò lówó gbogbo ohun tó bá lè ti ènìyàn láti se irú ìyàsòtò bé è.

Abala kejo.

16Enì kòòkan lórilè-èdè, lò ni ètó si àtunse td jojú ni ilé-ejò fún ìwà tó lòdi si ètó omonìyàn, td kò-seé-má-nìi gégé bd se wà labé òfin àti bi òfin-ìpìlè se là á silè-

Abala kesàn-án.

17A kò gbodò sàdédé fi òfin mú ènìyàn tábi ki a kàn gbé ènìyàn tì mòlé, tàbi ki a lé ènìyàn jáde ni ìlú lá inídií.

Abala kewáá.

18Eni kòòkan ti a bá fi èsùn kàn ló ni ètó tó dógba, tó si kún, láti sàlàyé ara rè ni gbañgba, niwájú ilé-ejó ti kò sègbè, ki won lè se ìpinnu lóri ètó àti ojúse rè nipa irú èsùn òràn didà ti a fi kàn àn.

Abala kokànlà.

  1. Enìkéni ti a fi èsùn kàn ni a gbodò gbà wi pé ó jàrè titi èbi rè yóò fi hàn lábé òfin nipasè ìdájó ti a se ni gbañgba ninú èyi ti eni ti a fi èsùn kàn yóò ti ni gbogbo ohun ti ó nilò láti fi se àwijàre ara rè-
  2. A kò gbodò dá èbi èsè fún enìkéni fún pé ó hu ìwà kan tàbi pé ó se àwon àfojúfò kàn nigbà tó jé pé lásìkò ti èyi selè, irú ìwà béè tábi irú àfojdfò béè kò lòdi si òfin orilè-èdè eni náà tábi òfin àwon orilè-èdè àgbàyé mìíràn. Bákan náà, ìjeniyà ti a lè fún eni tó désè kò gbodò ju èyi tó wà ni ìmúlò ni àsìkò ti eni náà dà èsè rè.

Abala kejìlà.

19Eni kòokan ló ni ètó pé ki a mà sàdédé se àyojúràn si òrò ìgbési ayé rè, tábi si òrò ebi rè tàbi si òrò ìdilé rè tàbi ìwé ti a ko si i ; a kò sì gbodò ba iyì àti orúko rè jé. Eni kòòkan ló ni ètó si ààbò lábé òfin kúrò lówó irú àyojdràn tàbi ìbanijé béè.

Abala ketàlá.

  1. Eni kòòkan ló ni ètó láti rìn káàkiri ni òmìnira ki ó sì fi ibi tó bá wù ü se ìbùgbé láàrin orilè-èdè rè.
  2. Eni kòòkan ló ni ètó láti kurò lórilè-èdè yòówù kó jè, tó fi mo orilè-èdè tirè, ki ó sì tún padà si orilè-èdè tirè nigbà td bá wù ú.

Abala kerìnlá.

  1. Enì kòòkan ló ni ètó láti wá ààbò àti láti je ànfani ààbò yìi ni orilè-èdè mìiràn nigbà tí a bá n se inúnibini si i.
  2. A kò lè lo ètò yii fún eni ti a bá pè lèjó tó dájú nitori èsè ti kò je mò òrò ìsèlú tàbi ohun mìiràn tí o se ti kò bá ète àti ìgbékalè Ajo-ìsòkan orilè-èdè àgbayé mu.

20Abala keèédógún.

  1. Eni kòòkan ló ni ètó láti jé omo orilè-èdè kan.
  2. A kò lè sàdédé gba ètó jijé omo orilè-èdè eni lówó enìkèni láìnidìi tàbi ki a kò fún enìkèni láti yàn láti jè omo orilè-èdè mìiràn.

Abala kerìndinlógún.

  1. Tokùnrin tobìnrin td bá ti bàlágà ló ni ètó láti fé ara won, ki wón sì dá ebi ti won silè laìsi ìkanilápá-kò kankan nipa èyà won, tàbi orilè-èdè won tàbi èsin won. Etó won dógba nínü ìgbeyàwd ìbáà jé nigbà ti won wà papò tàbi léyìn ti wón bà ko ara won.
  2. A kò gbodò se ìgbeyàwó kan láìjé pé àwon ti ó fé fé ara won ni òmìnira àtokànwà tò péye láti yàn fúnra won.
  3. Ebi jé ìpìlè pàtàkì àdànidà ni àwùjo, ò sì ni ètò pé ki àwùjo àti orilè-èdè ò dààbò bò ó.

Abala ketàdinlógún.

  1. Eni kòòkan ló ni ètó láti dà ohun ini ara rè ni tábi láti ni in papo pèlli àwon mìiràn.
  2. A kò lè sàdédé gba ohun ini eni kan lówó rè làìnidìi.

Abala kejìdìnlógùn.

21Eni kòòkan ló ni ètó si òmìnira èrò, òmìnira èri-okàn àti òmìnira èsìn. Etó yìi sì gbani láàyè láti pààrò èsìn tàbi ìgbàgbo eni. O sì fún eyo eni kan tàbi àkójopò ènìyàn lààyè láti se èsìn won àti ìgbàgbó won bó se je mó ti ìkóni, ìsesi, ìjósìn àti ìmúse ohun ti wón gbàgbó yàlà ni ìkòkò tàbi ni gbangba.

Abala kokàndinlógun.

22Eni kòòkan ló ni ètó si òmìnira láti ni ìmoràn ti ó wù ú, ki ó sì so irú ìmòràn béè jàde ; ètó yìi gbani lààyè láti ni ìmòràn yòówù làìsi àtakò láti òdo enìkéni láti wàdìi òrò, láti gba ìmòràn lódò elòmiràn tàbi láti gbani niyànjú lónákónà láika ààlà orilè-èdè kankan kún.

Abala ogún.

  1. Eni kòòkan ló ni ètó si òmìnira láti pé jo pò àti láti dara pò mó àwon mìiràn ni àlàáfià.
  2. A kò lè fi ipá mú enìkéni dara pò mó egbé kankan.

Abala kokànlélógun.

  1. Eni kòòkan ló ni ètó láti kópa ninu ìsàkóso orilè-èdè rè, yálà fdnra rè tàbi nipasè àwon asojd ti a kò fi ipá yàn.
  2. Eni kòòkan ló ni ètó tó dógba láti se isé ìjoba ni orilè-èdè rè.
  3. Ifé àwon ènìyàn ìlú ni yóò jé òkúta ìpìlè fún àse ìjoba ; a ó máa fi ìfé yìi hàn nipasè ìbò tòóto ti a ó màa dì láti ìgbà dé ìgbà, nind èyi ti eni kòòkan yóò ni ètó si ìbò kan soso ti a dì ni ìkòkò tàbi nipasè irú onà ìdìbò mìiràn tí ó bà ird idibò béè mu.

Abala kejìlélógún.

23Eni koòkan gégé bi èyà ninú àwùjo ló ni ètó si ìdáàbò bò láti owo ìjoba àti láti jé ànfàni àwon ètó tí ó bá orò-ajé, ìwà láwùjo àti àsà àbinibi mu ; àwon ètó ti ó jé kò-seé-má-nìi fún iyì àti ìdàgbàsókè èdá ènìyàn, nipa akitiyan ninú orilè¬èdè àti ìfowdsowd pò láàrin àwon orilè-èdè ni ìbámu pèlú ètò àti ohun àlùmònì orilè-èdè kòòkan.

Abala ketàlélógún.

  1. Eni kòòkan ló ni ètó láti sisé, láti yan ird isé tí ó wù d, lábé àdéhùn ti ó tó ti ó sì tún rorùn, ki ó sì ni ààbò kúrò lówó àìrisé se.
  2. Eni kòòkan ló ni ètó láti gba iye owó ti ó dógba fún irú isé kan náà, láìsi ìyàsótò kankan.
  3. Eni kòòkan ti ó bá n sisé ni ètó láti gba owó o$ù ti ó tó ti yóò sì tó fún òun àti ebi rè láti gbé ayé ti ó bu iyì kún ènìyàn ; a sì lè fi kún owó yìi nipasè orisìi àwon ètò ìrànlówó mìiràn nigbà ti ó bá ye.
  4. Eni kòòkan ló ni ètó láti dá egbé òsìsé silè àti láti dara pò mó irú egbé béè láti dáàbò bo àwon ohun ti ó je é lógún.

Abala kerìnlélógún.

24Eni kòòkan ló ni ètó si ìsinmi àti fàájì pèlú àkókò ti kò pò jù lénu i$é àti àsìkò ìsinmi lénu isé láti ìgbà dé ìgbà ti a ó sanwó fún.

Abala keèédógbòn.

  1. Eni kòòkan ló ni ètó láti gbé ìgbé ayé tó bójú mu ninú èyi ti òun àti ebi rè yóò wà ni ìlera àti àlàáfià, ti won yóò sì ni oúnje, aso, ilégbèé, àti ànfàni fún ìwòsàn àti gbogbo ohun tó lè mú èdá gbé ìgbé ayé rere. Bákan náà, enì kòòkan ló tún ni ààbò nigbà àìnisélòwò, nigbà àìsàn, nigbà td bà di aláàbò-ara, ni ipò opó, nigbà ogbò rè tàbi ìgbà mìiràn ti ènìyàn kò ni ònà láti ri oúnje òòjò, ti eléyìi kì i sì ì se èbi olúwa rè.
  2. A ni láti pèsè ìtòjú àti ìrànlówó pàtàkì fun àwon abìyamo àti àwon omodé. Gbogbo àwon omodé yòò màa je àwon ànfàni ààbò kan nàà ninú àwùjo yálà àwon òbi won fé ara won ni tàbi won kò fé ara won.

Abala kerìndinlògbòn.

  1. Eni kòòkan ló ni ètó láti kò èkó. O kéré tàn, èkó gbodò jé òfé ni àwon ilé-èkó alàkòóbèrè. Ekó ni ilé-èkò alàkòòbèrè yìi sì gbodò jé dandan. A gbodò pésè èkó isé-owó, àti ti ìmò-èro fun àwon ènìyàn làpapò. Anfàni tó ddgba ni ilé-èkó giga gbodò wà ni àrówòtó gbogbo eni tó bà tó si.
  2. Ohun ti yóò jé ète èkó ni láti mú ìlosiwájú tó péye bà èdá ènìyàn, ki d sì tubò ri i pé àwon ènìyàn bòwò fún ètd omonìyàn àti àwon òmìnira won, td jé kò-seé-mà-nìi. Etò èkó gbodò lè ri i pé èmi ìgbòra-eni-yé, ìbàgbépò àlààfià , àti ìfé Òré-si-òré wà lààrin orilè-èdé, láàrin èyà kan si òmiràn àti lààrin elésìn kan si òmiràn. Etò-èkd sì gbodò kún àwon akitiyan Ajo-ìsòkan oriiè-èdè àgbàyé lówó láti ri-i pé àlààfià fidi múlè-
  3. Awon òbi ló ni ètò tó ga jù lo láti yan èkó ti wón bà fé fun àwon omo won.

Abala ketàdinldgbòn.

  1. Eni kòòkan ló ni ètd laìjè pé a fi ipá mú un iati kópa ninú àpapò ìgbé ayé àwùjo rè, kí ó je igbádún gbogbo ohun àmúse wà ibè, ki ó sì kdpa ninú ìdàgbàsókè ìmò sáyensì àti àwon ànfàni td ri ti ibè jáde.
  2. Eni kòòkan lo ni ètó si ààbò ànfani ìmoyì àti ohun ini ti ó je yo láti inú isè yòówù ti d bá se ìbáà se ìmò sáyénsì, ìwé kiko tàbi isé onà.

25Abala kejìdinlógbòn.

26Enì kòòkan ló ni ètó si ètò ninú àwùjo rè àti ni gbogbo àwùjo àgbáyé nibi ti àwon ètó òmìnira ti a ti gbé kalè ninü ìkéde yìi ydò ti jé mimúse.

Abala kokàndinlógbón.

  1. Eni kòòkan ld ni àwon ojüse kan si àwùjo, nipasè èyi ti d fi lè seé se fün eni náà láti ni ìdàgbàsdkè kikún gègè bi èdá ènìyàn.
  2. Ofin ydò de enì kòòkan láti fi òwò àti ìmoyì ti tí td fün ètd ati òmìnira àwon elòmiràn nigbà ti eni náà bá ri lo àwon ètd àti òmìnira ara rè. Eyi wà ni ìbámu pèlú ònà tó ye, tó sì tó láti fi báni lò ninü àwùjo fün ire àti àlàáfià àwùjo náà ninü èyi ti ìjoba ydò wà lówó gbogbo ènìyàn.
  3. A kò gbodò lo àwon ètó àti òmìnira wònyi rárá, ni ònà yòdwù kd jè, tó bá lòdi si àwon ète àti ìgbékalè Ajo-àpapò orilè-èdè agbáyé.

Abala ogbòn.

27A kò gbodò túmò ohunkóhun ninú ìkéde yìi gégè bi ohun ti ò fún orilè-èdè kan tàbi àkdjopò àwon ènìyàn kan tàbi enìkéni ni ètó láti se ohunkóhun ti ydò mú ìparun bà èyikéyìi ninú àwon ètó àti òmìnira ti a kéde yìi.

Der Text und andere Elemente (Illustrationen, importierte Anhänge) stehen unter OpenEdition Books License, sofern nicht anders angegeben.

Diese digitale Publikation wurde durch automatische optische Zeichenerkennung erstellt.

Lesen

Open access

Kaufen

Suche in OpenEdition Search

Sie werden weitergeleitet zur OpenEdition Search